Luke 19:45-48

Jesu nínú tẹmpili

45 aÓ sì wọ inú tẹmpili lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde; 46Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò àwọn ọlọsa.”

47 bÓ sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹmpili, Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á. 48Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe; nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.

Copyright information for YorBMYO